Exodus 6:16-20


16 aÌwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn:
Gerṣoni, Kohati àti Merari.
Lefi lo ẹ̀tàndínlógóje (137) ọdún láyé.
17Àwọn ọmọ Gerṣoni ni ìran wọn ni:
Libni àti Ṣimei.
18Àwọn ọmọ Kohati ni:
Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli.
Kohati lo ẹ̀tàléláádóje (133) ọdún láyé.
19Àwọn ọmọ Merari ni:
Mahili àti Muṣi.
Ìwọ̀nyí ni ìran Lefi gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn.

20 bAmramu sì fẹ́ Jokebedi arábìnrin baba rẹ̀ ní ìyàwó. Jokebedi sì bí Aaroni àti Mose fún un.
Amramu lo ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún láyé.
Copyright information for YorBMYO